Mátíù 27:34 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 34 wọ́n fún un ní wáìnì tí wọ́n pò mọ́ òróòro* mu;+ àmọ́ nígbà tó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. Máàkù 15:23 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 23 Ibẹ̀ ni wọ́n ti fẹ́ fún un ní wáìnì tí wọ́n fi òjíá sí kí wáìnì náà lè le,+ àmọ́ kò mu ún.