17 Nígbà náà, Áhítófẹ́lì sọ fún Ábúsálómù pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n yan ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ọkùnrin, kí a sì gbéra láti lépa Dáfídì lálẹ́ òní. 2 Màá yọ sí i nígbà tó bá ti rẹ̀ ẹ́, tí kò sì ní agbára kankan,+ màá mú kí ẹ̀rù bà á; gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ á sá lọ, màá sì pa ọba nìkan.+