23 Nígbà tí Áhítófẹ́lì rí i pé wọn ò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn òun, ó de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì lọ sí ilé rẹ̀ ní ìlú rẹ̀.+ Lẹ́yìn tó ti sọ ohun tí agbo ilé rẹ̀+ máa ṣe, ó pokùn so.+ Torí náà, ó kú, wọ́n sì sin ín sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba ńlá rẹ̀ sí.