ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 4:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Júdà àti Ísírẹ́lì ń gbé lábẹ́ ààbò ní gbogbo ọjọ́ ayé Sólómọ́nì, kálukú lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà.

  • 1 Kíróníkà 22:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Wò ó! Wàá bí ọmọkùnrin kan+ tó máa jẹ́ ẹni àlàáfíà,* màá sì fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó yí i ká,+ Sólómọ́nì*+ ni orúkọ tí a máa pè é, màá sì fi àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ jíǹkí Ísírẹ́lì ní ìgbà ayé rẹ̀.+

  • Àìsáyà 2:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Ó máa ṣe ìdájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,

      Ó sì máa yanjú ọ̀rọ̀* láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn.

      Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀,

      Wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.+

      Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,

      Wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+

  • Àìsáyà 9:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Torí a ti bí ọmọ kan fún wa,+

      A ti fún wa ní ọmọkùnrin kan;

      Àkóso* sì máa wà ní èjìká rẹ̀.+

      Orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́ Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn,+ Ọlọ́run Alágbára,+ Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́