10 Ní ọjọ́ tí o dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní Hórébù, Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn èèyàn náà jọ sọ́dọ̀ mi kí n lè mú kí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi,+ kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi+ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n á fi wà láàyè lórí ilẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ àwọn ọmọ wọn.’+