-
Diutarónómì 1:43Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
43 Mo wá bá yín sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ ò gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ kẹ̀yìn sí àṣẹ Jèhófà, ẹ sì ṣorí kunkun* pé ẹ máa gun òkè náà lọ.
-
-
2 Àwọn Ọba 17:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Jèhófà lo gbogbo wòlíì rẹ̀ àti gbogbo aríran+ rẹ̀ láti máa kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì àti Júdà pé: “Ẹ kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú yín!+ Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìlànà mi mọ́, bó ṣe wà nínú gbogbo òfin tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, tí mo sì fi rán àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín.” 14 Àmọ́ wọn ò gbọ́, wọ́n sì ya alágídí bí* àwọn baba ńlá wọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run wọn.+
-