27 Nítorí èyí, o fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn,+ wọ́n sì ń kó wàhálà bá wọn.+ Àmọ́, wọ́n á ké pè ọ́ ní àkókò wàhálà wọn, ìwọ náà á sì gbọ́ láti ọ̀run; nítorí àánú ńlá rẹ, wàá fún wọn ní olùgbàlà láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.+
9 Àmọ́, mo gbé ìgbésẹ̀ torí orúkọ mi, kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè, láàárín àwọn tí wọ́n ń gbé.+ Torí nígbà tí mo mú wọn* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mo jẹ́ kí wọ́n* mọ̀ mí níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè yìí.+