2 Lẹ́yìn èyí, mo wà nínú agbára ẹ̀mí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, sì wò ó! ìtẹ́ kan wà ní àyè rẹ̀ ní ọ̀run, ẹnì kan sì jókòó sórí ìtẹ́ náà.+ 3 Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ náà rí bí òkúta jásípérì+ àti òkúta sádísì, òṣùmàrè kan tó dà bí òkúta émírádì sì wà yí ká ìtẹ́ náà.+