16 Àwọn èèyàn tí wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún yóò di òkú tí wọ́n á gbé jù sí àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù nítorí ìyàn àti idà. Ẹnì kankan kò sì ní sin wọ́n,+ látorí àwọn fúnra wọn dórí àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin wọn, torí màá mú àjálù tí ó tọ́ sí wọn bá wọn.’+
4 ‘Àrùn burúkú ni yóò pa wọ́n,+ ẹnì kankan ò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní sin wọ́n; wọ́n á dà bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀.+ Idà àti ìyàn ni yóò pa wọ́n,+ òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀.’