-
Ẹ́kísódù 23:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Díẹ̀díẹ̀ ni màá lé wọn kúrò níwájú yín, títí ẹ ó fi bí àwọn ọmọ, tí ẹ ó sì gba ilẹ̀ náà.+
-
-
Jóṣúà 24:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Torí náà, mo mú kí àwọn èèyàn rẹ̀wẹ̀sì* kí ẹ tó dé ọ̀dọ̀ wọn, ìyẹn sì mú kí wọ́n sá kúrò níwájú yín,+ ìyẹn ọba Ámórì méjèèjì. Kì í ṣe idà yín tàbí ọfà yín ló ṣe èyí.+ 13 Mo wá fún yín ní ilẹ̀ tí ẹ ò ṣiṣẹ́ fún àti àwọn ìlú tí ẹ ò kọ́,+ ẹ sì ń gbé inú wọn. Ẹ tún ń jẹ àwọn èso ọgbà àjàrà àti àwọn èso igi ólífì tí ẹ ò gbìn.’+
-
-
1 Àwọn Ọba 4:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Júdà àti Ísírẹ́lì ń gbé lábẹ́ ààbò ní gbogbo ọjọ́ ayé Sólómọ́nì, kálukú lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà.
-