26 Ó sọ pé: “Tí ẹ bá ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín délẹ̀délẹ̀, tí ẹ ṣe ohun tó tọ́ ní ojú rẹ̀, tí ẹ pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ń tẹ̀ lé gbogbo ìlànà rẹ̀,+ mi ò ní mú kí ìkankan ṣe yín nínú àwọn àrùn tí mo mú kó ṣe àwọn ará Íjíbítì,+ torí èmi Jèhófà ló ń mú yín lára dá.”+