-
Ẹ́kísódù 1:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Nígbà tó yá, ọba tuntun tí kò mọ Jósẹ́fù jẹ ní Íjíbítì. 9 Ó sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ wò ó! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pọ̀ jù wá lọ, wọ́n sì tún lágbára jù wá lọ.+ 10 Ẹ jẹ́ ká dọ́gbọ́n kan. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n á máa pọ̀ sí i. Tí ogun bá sì dé, wọ́n á dara pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa láti gbógun jà wá, wọ́n á sì kúrò nílùú.”
-
-
Ẹ́sítà 3:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Àmọ́ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn láti pa* Módékáì nìkan, torí wọ́n ti sọ fún un nípa àwọn èèyàn Módékáì. Nítorí náà, Hámánì bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasuérúsì run, ìyẹn gbogbo àwọn èèyàn Módékáì.
-