21 Torí náà, Séébà àti Sálímúnà sọ fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ dìde, kí o sì pa wá, torí bí ẹnì kan bá ṣe lágbára tó la fi ń mọ̀ bóyá ọkùnrin ni.” Gídíónì wá dìde, ó pa Séébà àti Sálímúnà,+ ó sì mú ohun ọ̀ṣọ́ tó rí bí òṣùpá tó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.