ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́sírà 3:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn kọrin,+ wọ́n ń yin Jèhófà, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí Ísírẹ́lì sì wà títí láé.”+ Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn kígbe sókè láti yin Jèhófà nítorí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀.

  • Jeremáyà 33:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ní ibí yìí tí ẹ̀ ń sọ pé ó jẹ́ aṣálẹ̀, tí kò sí èèyàn tàbí ẹran ọ̀sìn níbẹ̀, ní àwọn ìlú Júdà àti àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù tó ti di ahoro, tí kò sí èèyàn tàbí ẹni tó ń gbé ibẹ̀ àti ẹran ọ̀sìn, ibẹ̀ ni a ó tún ti pa dà gbọ́ 11 ìró ayọ̀ àti ìró ìdùnnú,+ ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó, ohùn àwọn tó ń sọ pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, nítorí Jèhófà jẹ́ ẹni rere;+ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì wà títí láé!”’+

      “‘Wọ́n á mú ẹbọ ìdúpẹ́ wá sínú ilé Jèhófà,+ nítorí màá mú àwọn tí wọ́n kó lọ sí oko ẹrú láti ilẹ̀ náà pa dà wá bíi ti ìbẹ̀rẹ̀,’ ni Jèhófà wí.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́