17 Èlíṣà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, ó sọ pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́, la ojú rẹ̀, kó lè ríran.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì ríran, wò ó! àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun oníná+ kún agbègbè olókè náà, wọ́n sì yí Èlíṣà ká.+
10 Ẹ rí i pé ẹ ò kẹ́gàn ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí, torí mò ń sọ fún yín pé ìgbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run máa ń wo ojú Baba mi tó wà ní ọ̀run.+