Sáàmù 21:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 21 Jèhófà, inú agbára rẹ ni ọba ti ń yọ̀;+Wo bí ó ṣe ń yọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ!+ Sáàmù 21:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 Ó béèrè ẹ̀mí lọ́wọ́ rẹ, o sì fún un,+Ẹ̀mí gígùn,* títí láé àti láéláé. Òwe 3:1, 2 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Ọmọ mi, má gbàgbé ẹ̀kọ́* mi,Sì jẹ́ kí ọkàn rẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, 2 Nítorí wọ́n á fi ọ̀pọ̀ ọjọ́Àti ẹ̀mí gígùn pẹ̀lú àlàáfíà kún un fún ọ.+
3 Ọmọ mi, má gbàgbé ẹ̀kọ́* mi,Sì jẹ́ kí ọkàn rẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, 2 Nítorí wọ́n á fi ọ̀pọ̀ ọjọ́Àti ẹ̀mí gígùn pẹ̀lú àlàáfíà kún un fún ọ.+