25 Ó dájú pé o ò ní hùwà báyìí, pé kí o pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú, tó fi jẹ́ pé ohun kan náà+ ló máa ṣẹlẹ̀ sí olódodo àti ẹni burúkú! Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.+ Ṣé Onídàájọ́ gbogbo ayé kò ní ṣe ohun tó tọ́ ni?”+
31 Torí ó ti dá ọjọ́ kan tó máa fi òdodo ṣèdájọ́ + ayé láti ọwọ́ ọkùnrin kan tó ti yàn, ó sì ti pèsè ẹ̀rí tó dájú fún gbogbo èèyàn bó ṣe jí i dìde kúrò nínú ikú.”+