13 Ni méjì lára àwọn ọkùnrin aláìníláárí bá wọlé, wọ́n jókòó síwájú rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ta ko Nábótì níwájú àwọn èèyàn náà, wọ́n ní: “Nábótì ti sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti sí ọba!”+ Lẹ́yìn náà, wọ́n mú un lọ sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa.+