15 Ọlọ́run wá sọ fún Mósè lẹ́ẹ̀kan sí i pé:
“Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù+ ló rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi títí láé,+ bí wọ́n á sì ṣe máa rántí mi láti ìran dé ìran nìyí.