-
Jóòbù 38:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ta ló sì fi àwọn ilẹ̀kùn sé òkun,+
Nígbà tó tú jáde látinú ikùn,*
9 Nígbà tí mo fi ìkùukùu wọ̀ ọ́ láṣọ,
Tí mo sì fi ìṣúdùdù tó kàmàmà wé e,
10 Nígbà tí mo pààlà ibi tí mo fẹ́ kó dé,
Tí mo sì fi àwọn ọ̀pá àtàwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ sáyè wọn,+
-
Sáàmù 33:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ó gbá omi òkun jọ bí ìsédò;+
Ó fi omi tó ń ru gùdù sínú àwọn ilé ìṣúra.
-
-
Òwe 8:29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Nígbà tó pàṣẹ fún òkun
Pé kí omi rẹ̀ má kọjá àṣẹ tó pa fún un,+
Nígbà tó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,*
-
-
-