5 Tí ẹ bá ṣègbọràn sí ohùn mi délẹ̀délẹ̀, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, ó dájú pé ẹ ó di ohun ìní mi pàtàkì nínú gbogbo èèyàn,+ torí gbogbo ayé jẹ́ tèmi.+ 6 Ẹ ó di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.’+ Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyẹn.”