30 Ni Jékọ́bù bá sọ fún Síméónì àti Léfì+ pé: “Wàhálà ńlá lẹ kó mi sí yìí,* torí ẹ máa mú kí àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì tó ń gbé ilẹ̀ yìí kórìíra mi. Mo kéré níye, ó sì dájú pé wọ́n á kóra jọ láti bá mi jà, wọ́n á sì pa mí run, èmi àti ilé mi.”