-
Ẹ́kísódù 9:23-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Mósè wá na ọ̀pá rẹ̀ sí ọ̀run, Jèhófà sì mú kí ààrá sán, yìnyín bọ́, iná* sọ̀ kalẹ̀, Jèhófà sì ń mú kí òjò yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀ Íjíbítì. 24 Yìnyín bọ́, iná sì ń kọ mànà láàárín yìnyín náà. Yìnyín náà pọ̀ gan-an; kò sí irú rẹ̀ rí nílẹ̀ náà látìgbà tí Íjíbítì ti di orílẹ̀-èdè.+ 25 Yìnyín náà bọ́ lu gbogbo ohun tó wà nínú oko ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, látorí èèyàn dórí ẹranko, ó run gbogbo ewéko, ó sì run gbogbo igi oko.+ 26 Ilẹ̀ Góṣénì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nìkan ni yìnyín náà ò dé.+
-