4 Ó gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn, ó lo irinṣẹ́ àwọn tó ń fín nǹkan láti fi mọ ọ́n, ó sì fi ṣe ère* ọmọ màlúù.+ Wọ́n wá ń sọ pé: “Ìwọ Ísírẹ́lì, Ọlọ́run rẹ nìyí, òun ló mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+
12 Jèhófà sì sọ fún mi pé, ‘Gbéra, tètè sọ̀ kalẹ̀ kúrò níbí, torí pé àwọn èèyàn rẹ tí o mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ti hùwà ìbàjẹ́.+ Wọ́n ti yára kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa rìn. Wọ́n ti ṣe ère onírin* fún ara wọn.’+