11 Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ṣebí mo gbà yín lọ́wọ́ Íjíbítì+ àti lọ́wọ́ àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Ámónì, àwọn Filísínì,+ 12 àwọn ọmọ Sídónì, Ámálékì àti Mídíánì, nígbà tí wọ́n ń fìyà jẹ yín? Nígbà tí ẹ ké pè mí, mo gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn.