25 Nígbà náà, Jésù sọ pé: “Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, mo yìn ọ́ ní gbangba, torí pé o fi àwọn nǹkan yìí pa mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ọmọdé.+
46 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n rí i nínú tẹ́ńpìlì, ó jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, ó ń fetí sí wọn, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè. 47 Àmọ́ léraléra ni ẹnu ń ya gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye tó ní àti bó ṣe ń dáhùn.+