1 Sámúẹ́lì 30:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Ìdààmú bá Dáfídì gan-an, torí àwọn ọkùnrin náà ń sọ pé àwọn máa sọ ọ́ lókùúta, torí inú bí gbogbo àwọn ọkùnrin náà gan-an, nítorí àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn tí wọ́n kó lọ. Àmọ́ Dáfídì fún ara rẹ̀ lókun látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.+ Sáàmù 62:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 62 Ní tòótọ́, mo* dúró jẹ́ẹ́ de Ọlọ́run. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá.+ Àìsáyà 30:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ mi, tí ẹ sì sinmi, ẹ máa rígbàlà;Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”+ Àmọ́ kò wù yín.+ Ìdárò 3:26 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 26 Ó dáa kí èèyàn dúró jẹ́ẹ́*+ de ìgbàlà Jèhófà.+
6 Ìdààmú bá Dáfídì gan-an, torí àwọn ọkùnrin náà ń sọ pé àwọn máa sọ ọ́ lókùúta, torí inú bí gbogbo àwọn ọkùnrin náà gan-an, nítorí àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn tí wọ́n kó lọ. Àmọ́ Dáfídì fún ara rẹ̀ lókun látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.+
15 Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ mi, tí ẹ sì sinmi, ẹ máa rígbàlà;Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”+ Àmọ́ kò wù yín.+