41 Torí náà, dìde, Jèhófà Ọlọ́run, wá síbi ìsinmi rẹ,+ ìwọ àti Àpótí agbára rẹ. Jèhófà Ọlọ́run, fi aṣọ ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ, sì jẹ́ kí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yọ̀ nínú ohun rere.+ 42 Jèhófà Ọlọ́run, má ṣe kọ ẹni àmì òróró rẹ sílẹ̀.+ Rántí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ.”+