7 Ìgbà náà ni Nátánì sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ ni ọkùnrin náà! Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Èmi ni mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì,+ mo sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù.+
9 Kí ló dé tí o kò fi ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sí, tí o wá ṣe ohun tó burú lójú rẹ̀? O fi idà pa+ Ùráyà ọmọ Hétì! Lẹ́yìn náà, o sọ ìyàwó rẹ̀ di tìrẹ+ lẹ́yìn tí o ti mú kí idà àwọn ọmọ Ámónì pa á.+
6Ẹ̀yin ará, tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kó tó mọ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ kúnjú ìwọ̀n nípa tẹ̀mí sapá láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́* tọ́ ẹni náà sọ́nà.+ Àmọ́ kí ẹ máa kíyè sí ara yín lójú méjèèjì,+ kí a má bàa dẹ ẹ̀yin náà wò.+