9 Lẹ́yìn náà, wọ́n kéde káàkiri Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé kí wọ́n mú owó orí mímọ́+ tí Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ bù lé Ísírẹ́lì ní aginjù, wá fún Jèhófà. 10 Inú gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn èèyàn náà dùn,+ wọ́n ń mú ọrẹ wá, wọ́n sì ń jù ú sínú àpótí náà títí ó fi kún.