-
2 Sámúẹ́lì 7:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ní báyìí, sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo mú ọ láti ibi ìjẹko, pé kí o má da agbo ẹran mọ́,+ kí o lè wá di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+ 9 Màá wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí o bá lọ,+ màá sì mú* gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ;+ màá jẹ́ kí orúkọ rẹ lókìkí gan-an+ bí orúkọ àwọn ẹni ńlá tó wà láyé.
-