16 Ohun mẹ́fà wà tí Jèhófà kórìíra;
Bẹ́ẹ̀ ni, ohun méje tó jẹ́ ohun ìríra fún un:
17 Ojú ìgbéraga,+ ahọ́n èké+ àti ọwọ́ tó ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,+
18 Ọkàn tó ń gbèrò ìkà+ àti ẹsẹ̀ tó ń sáré tete láti ṣe ibi,
19 Ẹlẹ́rìí èké tí kò lè ṣe kó má parọ́+
Àti ẹni tó ń dá awuyewuye sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.+