44 Ọ̀dọ̀ Èṣù bàbá yín lẹ ti wá, ẹ sì fẹ́ ṣe àwọn ìfẹ́ ọkàn bàbá yín.+ Apààyàn ni ẹni yẹn nígbà tó bẹ̀rẹ̀,+ kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, torí pé òtítọ́ ò sí nínú rẹ̀. Tó bá ń pa irọ́, ṣe ló ń sọ irú ẹni tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́, torí pé òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́.+