38 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi gan-an, àní títí dé ikú. Ẹ dúró síbí, kí ẹ sì máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”+ 39 Ó lọ síwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé:+ “Baba mi, tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife+ yìí ré mi kọjá. Síbẹ̀, kì í ṣe bí mo ṣe fẹ́, àmọ́ bí ìwọ ṣe fẹ́.”+