-
Diutarónómì 6:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 “Èyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fi lélẹ̀ láti kọ́ yín, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́ tí ẹ bá ti sọdá sí ilẹ̀ tí ẹ máa gbà, 2 kí ẹ lè máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin àti àṣẹ rẹ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín mọ́, ẹ̀yin àti ọmọ yín àti ọmọ ọmọ yín,+ ní gbogbo ọjọ́ ayé yín, kí ẹ̀mí yín lè gùn.+
-
-
Diutarónómì 30:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Mò ń fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí ọ lónìí, pé mo ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ègún;+ yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè,+ ìwọ àti àwọn àtọmọdọ́mọ+ rẹ, 20 nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, kí o máa fetí sí ohùn rẹ̀, kí o sì rọ̀ mọ́ ọn,+ torí òun ni ìyè rẹ, òun ló sì máa mú kí o pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.”+
-
-
1 Pétérù 3:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Torí “ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ràn ìgbésí ayé rẹ̀, tó sì fẹ́ ẹ̀mí gígùn gbọ́dọ̀ ṣọ́ ahọ́n rẹ̀ kó má bàa sọ ohun búburú,+ kó má sì fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀tàn. 11 Kí ó jáwọ́ nínú ohun búburú,+ kó sì máa ṣe rere;+ kó máa wá àlàáfíà, kó sì máa lépa rẹ̀.+ 12 Nítorí ojú Jèhófà* wà lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn;+ àmọ́ Jèhófà* kọjú ìjà sí àwọn tó ń ṣe ohun búburú.”+
-