21 Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Dáníẹ́lì sọ fún ọba pé: “Ìwọ ọba, kí ẹ̀mí rẹ gùn títí láé. 22 Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún náà lẹ́nu,+ wọn ò sì ṣe mí léṣe,+ torí ó rí i pé mi ò mọwọ́ mẹsẹ̀; mi ò sì ṣe ohun burúkú kankan sí ìwọ ọba.”
13 Kò sí àdánwò kankan tó ti bá yín àfi èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn.+ Àmọ́ Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra,+ ṣùgbọ́n nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.+