21 Torí náà, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Màá fi fún un kó lè di ìdẹkùn fún un, kí ọwọ́ àwọn Filísínì lè tẹ̀ ẹ́.”+ Sọ́ọ̀lù bá sọ fún Dáfídì lẹ́ẹ̀kejì pé: “Wàá di àna* mi lónìí yìí.”
25 Sọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún Dáfídì nìyí, ‘Ọba ò fẹ́ nǹkan ìdána kankan,+ àfi ọgọ́rùn-ún (100) adọ̀dọ́+ àwọn Filísínì, kó lè gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.’” Torí Sọ́ọ̀lù ń gbèrò pé kí Dáfídì ti ọwọ́ àwọn Filísínì ṣubú.