-
Diutarónómì 7:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 “Kì í ṣe torí pé ẹ̀yin lẹ pọ̀ jù nínú gbogbo èèyàn ni Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ yín tó sì yàn yín,+ ẹ̀yin lẹ kéré jù nínú gbogbo èèyàn.+ 8 Àmọ́ torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín, tó sì ṣe ohun tó búra fún àwọn baba ńlá yín+ pé òun máa ṣe ni Jèhófà ṣe fi ọwọ́ agbára mú yín kúrò, kó lè rà yín pa dà kúrò ní ilé ẹrú,+ kúrò lọ́wọ́* Fáráò ọba Íjíbítì.
-