-
Ìṣe 4:25-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 tó sì tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ gbẹnu Dáfídì+ baba ńlá wa tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ sọ pé: ‘Kí nìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń ṣe awuyewuye, tí àwọn èèyàn sì ń ṣe àṣàrò lórí ohun asán? 26 Àwọn ọba ayé dúró, àwọn alákòóso sì kóra jọ láti dojú kọ Jèhófà* àti ẹni àmì òróró* rẹ̀.’+ 27 Ní tòótọ́, Hẹ́rọ́dù àti Pọ́ńtíù Pílátù+ pẹ̀lú àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn èèyàn Ísírẹ́lì kóra jọ ní ìlú yìí láti dojú kọ Jésù, ìránṣẹ́ rẹ mímọ́, ẹni tí o fòróró yàn,+ 28 kí wọ́n lè ṣe àwọn ohun tí o ti pinnu nípasẹ̀ ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ràn rẹ pé kó ṣẹlẹ̀.+
-