Diutarónómì 23:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń rìn kiri nínú ibùdó rẹ+ láti gbà ọ́, kó sì fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́. Kí ibùdó rẹ máa wà ní mímọ́,+ kó má bàa rí ohunkóhun tí kò bójú mu láàárín rẹ, kó sì pa dà lẹ́yìn rẹ. Sáàmù 132:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Nítorí Jèhófà ti yan Síónì;+Ó fẹ́ kó jẹ́ ibùgbé rẹ̀, ó ní:+ Àìsáyà 12:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Ké jáde, kí o sì kígbe ayọ̀, ìwọ* tó ń gbé ní Síónì,Torí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tóbi láàárín rẹ.”
14 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń rìn kiri nínú ibùdó rẹ+ láti gbà ọ́, kó sì fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́. Kí ibùdó rẹ máa wà ní mímọ́,+ kó má bàa rí ohunkóhun tí kò bójú mu láàárín rẹ, kó sì pa dà lẹ́yìn rẹ.