5 Kì í ṣe torí pé o jẹ́ olódodo tàbí olóòótọ́ nínú ọkàn rẹ ló máa jẹ́ kí o lọ gba ilẹ̀ wọn. Àmọ́ ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè yìí ló máa mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lé wọn kúrò níwájú rẹ,+ kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá yín, Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Jékọ́bù+ sì lè ṣẹ.