27 Ṣé ọkùnrin kan lè wa iná jọ sí àyà rẹ̀, kí ẹ̀wù rẹ̀ má sì jó?+
28 Tàbí ṣé ọkùnrin kan lè rìn lórí ẹyin iná, kó má sì jó o lẹ́sẹ̀?
29 Bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún ẹni tó bá ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya ọmọnìkejì rẹ̀;
Kò sí ẹni tó fọwọ́ kàn án tó máa lọ láìjìyà.+