7 Ọgbọ́n ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ,+ torí náà ní ọgbọ́n,
Pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye.+
8 Jẹ́ kó níyì gan-an lójú rẹ, yóò sì gbé ọ ga.+
Yóò bọlá fún ọ nítorí pé o gbá a mọ́ra.+
9 Yóò fi òdòdó ẹ̀yẹ tó fani mọ́ra sí ọ lórí;
Yóò sì dé ọ ní adé ẹwà.”