-
Diutarónómì 24:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “O ò gbọ́dọ̀ rẹ́ alágbàṣe tó jẹ́ aláìní àti tálákà jẹ, ì báà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ tàbí àjèjì tó wà ní ilẹ̀ rẹ, nínú àwọn ìlú* rẹ.+ 15 Ọjọ́ yẹn gan-an ni kí o fún un ní owó iṣẹ́ rẹ̀,+ kí oòrùn tó wọ̀, torí pé aláìní ni, owó iṣẹ́ yìí ló sì ń gbé ẹ̀mí* rẹ̀ ró. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa fi ẹjọ́ rẹ sun Jèhófà, wàá sì jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.+
-