-
Ìṣe 16:23-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Lẹ́yìn tí wọ́n ti lù wọ́n nílùkulù, wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì pa àṣẹ pé kí ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n máa ṣọ́ wọn lójú méjèèjì.+ 24 Torí pé irú àṣẹ yẹn ni wọ́n pa fún un, ó jù wọ́n sí ẹ̀wọ̀n inú lọ́hùn-ún, ó sì de ẹsẹ̀ wọn mọ́ inú àbà.
25 Àmọ́ láàárín òru, Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń gbàdúrà, wọ́n ń fi orin yin Ọlọ́run,+ àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì ń fetí sí wọn.
-