-
2 Sámúẹ́lì 12:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Tinútinú ni mo fún ọ ní ilé ọ̀gá rẹ,+ tí mo fi àwọn ìyàwó ọ̀gá rẹ+ lé ọ lọ́wọ́, mo sì fún ọ ní ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà.+ Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, mo tún fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i fún ọ.+ 9 Kí ló dé tí o kò fi ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sí, tí o wá ṣe ohun tó burú lójú rẹ̀? O fi idà pa+ Ùráyà ọmọ Hétì! Lẹ́yìn náà, o sọ ìyàwó rẹ̀ di tìrẹ+ lẹ́yìn tí o ti mú kí idà àwọn ọmọ Ámónì pa á.+ 10 Wò ó, idà kò ní kúrò ní ilé rẹ láé,+ nítorí pé o kọ̀ mí, tí o sì sọ ìyàwó Ùráyà ọmọ Hétì di tìrẹ.’
-