-
1 Sámúẹ́lì 24:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Bí Dáfídì ṣe parí ọ̀rọ̀ tó sọ fún Sọ́ọ̀lù yìí, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Ṣé ohùn rẹ nìyí, Dáfídì ọmọ mi?”+ Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún kíkankíkan. 17 Ó sọ fún Dáfídì pé: “Òdodo rẹ ju tèmi lọ, torí o ti ṣe dáadáa sí mi, àmọ́ mo ti fi ibi san án fún ọ.+ 18 Bẹ́ẹ̀ ni, o ti sọ ohun rere tí o ṣe lónìí fún mi bí o kò ṣe pa mí nígbà tí Jèhófà fi mí lé ọ lọ́wọ́.+
-