ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 11:6, 7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Jèhófà sì sọ pé: “Wò ó! Èèyàn kan ni wọ́n, èdè kan+ ni wọ́n ń sọ, ohun tí wọ́n sì dáwọ́ lé nìyí. Kò ní sí ohun tí wọ́n ní lọ́kàn tí kò ní ṣeé ṣe fún wọn. 7 Wá! Jẹ́ ká+ lọ síbẹ̀ ká sì da èdè wọn rú, kí wọ́n má bàa gbọ́ èdè ara wọn mọ́.”

  • Jẹ́nẹ́sísì 50:19, 20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni Ọlọ́run ni? 20 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èrò ibi lẹ ní sí mi,+ Ọlọ́run mú kó yọrí sí rere, kó lè dá ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn sí, bó ti ń ṣe lónìí.+

  • Òwe 21:30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Kò sí ọgbọ́n tàbí òye tàbí ìmọ̀ràn tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró.+

  • Dáníẹ́lì 4:35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 35 Kò ka gbogbo àwọn tó ń gbé ayé sí nǹkan kan, ohun tó bá sì wù ú ló ń ṣe láàárín àwọn ọmọ ogun ọ̀run àti àwọn tó ń gbé ayé. Kò sí ẹni tó lè dá a dúró*+ tàbí kó sọ fún un pé, ‘Kí lo ṣe yìí?’+

  • Ìṣe 5:38, 39
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 Nítorí náà, níbi tọ́rọ̀ dé yìí, màá sọ fún yín pé kí ẹ má tojú bọ ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin yìí, ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Torí tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ èèyàn ni ète tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a ó bì í ṣubú; 39 àmọ́ tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ ò ní lè bì wọ́n ṣubú.+ Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀ẹ́ kàn rí i pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run jà ni.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́