-
Mátíù 21:23-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Lẹ́yìn tó lọ sínú tẹ́ńpìlì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tó ń kọ́ni, wọ́n sì sọ pé: “Àṣẹ wo lo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Ta ló sì fún ọ ní àṣẹ yìí?”+ 24 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Èmi náà á bi yín ní ohun kan, tí ẹ bá sọ fún mi, èmi náà á sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín: 25 Ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún àwọn èèyàn, ibo ló ti wá? Ṣé láti ọ̀run ni àbí látọ̀dọ̀ èèyàn?”* Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó láàárín ara wọn pé: “Tí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ ó máa sọ fún wa pé, ‘Kí ló wá dé tí ẹ ò gbà á+ gbọ́?’
-