ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 8:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ó ní: “Ohun tí ọba tó bá jẹ lórí yín máa lẹ́tọ̀ọ́ láti gbà nìyí:+ Á mú àwọn ọmọkùnrin yín,+ á sì fi wọ́n sínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀,+ á wá sọ wọ́n di agẹṣin rẹ̀,+ àwọn kan á sì ní láti máa sáré níwájú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀. 12 Á yan àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ àti àwọn olórí àràádọ́ta+ fún ara rẹ̀, àwọn kan á máa bá a túlẹ̀,+ wọ́n á máa bá a kórè,+ wọ́n á sì máa ṣe ohun ìjà fún un àti àwọn ohun èlò kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀.+

  • 1 Àwọn Ọba 4:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Sólómọ́nì ní àwọn alábòójútó méjìlá (12) tó ń bójú tó gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni láti pèsè oúnjẹ ní oṣù kan lọ́dún.+

  • 2 Kíróníkà 26:9, 10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Yàtọ̀ síyẹn, Ùsáyà kọ́ àwọn ilé gogoro+ sí Jerúsálẹ́mù lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ẹnubodè Igun+ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ẹnubodè Àfonífojì+ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ìtì Ògiri, ó sì mú kí wọ́n lágbára. 10 Ó tún kọ́ àwọn ilé gogoro+ sí aginjù, ó sì gbẹ́ kòtò omi púpọ̀* (nítorí ó ní ẹran ọ̀sìn tó pọ̀ gan-an); ó ṣe bákan náà ní Ṣẹ́fẹ́là àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀.* Ó ní àwọn àgbẹ̀ àti àwọn tó ń rẹ́wọ́ àjàrà ní àwọn òkè àti ní Kámẹ́lì, nítorí ó fẹ́ràn iṣẹ́ àgbẹ̀.

  • Orin Sólómọ́nì 8:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Sólómọ́nì ní ọgbà àjàrà+ kan ní Baali-hámọ́nì.

      Ó gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn tí á máa tọ́jú rẹ̀.

      Kálukú wọn á máa mú ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà wá fún èso rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́